Joshua 12

Orúkọ àwọn ọba tí a ṣẹ́gun

1 aÌwọ̀nyí ní àwọn ọba ilẹ̀ náà tí àwọn ará Israẹli ṣẹ́gun, tí wọ́n sì gba ilẹ̀ wọn ní ìlà-oòrùn Jordani, láti odò Arnoni dé Òkè Hermoni, pẹ̀lú gbogbo ìhà ìlà-oòrùn aginjù:

2Sihoni ọba àwọn Amori, tí ó jẹ ọba ní Heṣboni.
Ó ṣe àkóso láti Aroeri tí ń bẹ ní etí odò Arnoni, láti ìlú tó wà ní àárín Àfonífojì náà dé Odò Jabbok, èyí tí ó jẹ́ ààlà àwọn ọmọ Ammoni. Pẹ̀lú ìdajì àwọn ará Gileadi.
3Ó sì ṣe àkóso ní orí ìlà-oòrùn aginjù láti Òkun Kinnereti sí ìhà Òkun ti aginjù (Òkun Iyọ̀), sí Beti-Jeṣimoti, àti láti gúúsù lọ dé ìsàlẹ̀ ẹsẹ̀ òkè Pisga.
4Àti agbègbè Ogu ọba Baṣani, ọ̀kan nínú àwọn tí ó kù nínú àwọn ará Refaimu, ẹni tí ó jẹ ọba ní Aṣtarotu àti Edrei.
5Ó ṣe àkóso ní orí Òkè Hermoni, Saleka, Baṣani títí dé ààlà àwọn ènìyàn Geṣuri àti Maakati, àti ìdajì Gileadi dé ààlà Sihoni ọba Heṣboni.

6Mose ìránṣẹ́ Olúwa àti àwọn ọmọ Israẹli sì borí wọn. Mose ìránṣẹ́ Olúwa sì fi ilẹ̀ wọn fún àwọn ẹ̀yà Reubeni, àwọn ẹ̀yà Gadi àti ìdajì ẹ̀yà Manase kí ó jẹ́ ohun ìní wọn.

7Ìwọ̀nyí ní àwọn ọba ilẹ̀ náà tí Joṣua àti àwọn ọmọ Israẹli ṣẹ́gun ní ìhà ìwọ̀-oòrùn Jordani, láti Baali-Gadi ní Àfonífojì Lebanoni sí Òkè Halaki, èyí tí O lọ sí ọ̀nà Seiri (Joṣua sì fi ilẹ̀ wọn fún àwọn ẹ̀yà Israẹli ní ilẹ̀ ìní gẹ́gẹ́ bí ìpín ẹ̀yà wọn: 8ilẹ̀ òkè, ní ẹsẹ̀ òkè ní ìhà ìwọ̀-oòrùn òkè aginjù, ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè, ní aginjù àti nì gúúsù ilẹ̀ àwọn ará: Hiti, Amori, Kenaani, Peresi, Hifi àti àwọn ará Jebusi):

9Ọba Jeriko ọ̀kan
Ọba Ai (tí ó wà nítòsí Beteli) ọ̀kan
10Ọba Jerusalẹmu ọ̀kan
ọba Hebroni ọ̀kan
11Ọba Jarmatu ọ̀kan
ọba Lakiṣi ọ̀kan
12Ọba Egloni ọ̀kan
ọba Geseri ọ̀kan
13Ọba Debiri ọ̀kan
ọba Gederi ọ̀kan
14Ọba Horma ọ̀kan
ọba Aradi ọ̀kan
15Ọba Libina ọ̀kan
ọba Adullamu ọ̀kan
16Ọba Makkeda ọ̀kan
ọba Beteli ọ̀kan
17Ọba Tapua ọ̀kan
ọba Heferi ọ̀kan
18Ọba Afeki ọ̀kan
ọba Laṣaroni ọ̀kan
19Ọba Madoni ọ̀kan
ọba Hasori ọ̀kan
20Ọba Ṣimroni-Meroni ọ̀kan
ọba Akṣafu ọ̀kan
21Ọba Taanaki ọ̀kan
ọba Megido ọ̀kan
22Ọba Kedeṣi ọ̀kan
ọba Jokneamu ni Karmeli ọ̀kan
23Ọba Dori (ní Nafoti Dori) ọ̀kan
ọba Goyimu ní Gilgali ọ̀kan
24Ọba Tirsa ọ̀kan

gbogbo àwọn ọba náà jẹ́ mọ́kànlélọ́gbọ̀n.
Copyright information for YorBMYO